Orin Dafidi 37:9-16 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Nítorí pé a óo pa àwọn eniyan burúkú run;ṣugbọn àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé OLUWAni yóo jogún ilẹ̀ náà.

10. Ẹ fún eniyan burúkú ní ìgbà díẹ̀ sí i, yóo pòórá;ẹ̀ báà wá a títí ní ààyè rẹ̀, kò ní sí níbẹ̀.

11. Ṣugbọn àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ ni yóo jogún ilẹ̀ náà:wọn óo máa gbádùn ara wọn;wọn óo sì ní alaafia lọpọlọpọ.

12. Eniyan burúkú dìtẹ̀ mọ́ olódodo;ó sì ń wò ó bíi kíkú bíi yíyè.

13. Ṣugbọn OLUWA ń fi eniyan burúkú rẹ́rìn-ín,nítorí ó mọ̀ pé ọjọ́ ìparun rẹ̀ ń bọ̀.

14. Àwọn eniyan burúkú fa idà yọ, wọ́n sì kẹ́ ọfà wọnláti gba ẹ̀mí talaka ati aláìní,láti pa àwọn tí ń rìn lọ́nà ẹ̀tọ́.

15. Ṣugbọn idà wọn ni o óo fi pa wọ́n,ọrun wọn yóo sì dá.

16. Nǹkan díẹ̀ tí olódodo nídára ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ àwọn eniyan burúkú.

Orin Dafidi 37