Lefitiku 3:15-17 BIBELI MIMỌ (BM)

15. kíndìnrín rẹ̀ mejeeji, pẹlu ọ̀rá tí ó bò wọ́n níbi ìbàdí, ati ẹ̀dọ̀ rẹ̀.

16. Kí alufaa sun wọ́n lórí pẹpẹ náà gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun olóòórùn dídùn. Ti OLUWA ni gbogbo ọ̀rá ẹran.

17. Kí èyí jẹ́ ìlànà ayérayé fún àtìrandíran yín, ní gbogbo ibùgbé yín, pé ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ọ̀rá tabi ẹ̀jẹ̀.”

Lefitiku 3