Jobu 15:1-20 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Elifasi ará Temani bá dáhùn pé,

2. “Ṣé ọlọ́gbọ́n a máa fọ èsì tí kò mọ́gbọ́n lọ́wọ́?Kí ó dàbí àgbá òfìfo?

3. Kí ó máa jiyàn lórí ọ̀rọ̀ tí kò wúlò,tabi ọ̀rọ̀ tí kò níláárí?

4. Ṣugbọn ò ń kọ ìbẹ̀rù Ọlọrun sílẹ̀,o sì ń dènà adura níwájú rẹ̀.

5. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ni ó ń fa irú ọ̀rọ̀ tí ń ti ẹnu rẹ jáde,ètè rẹ sì kún fún àrékérekè.

6. Ẹnu rẹ ni ó dá ọ lẹ́bi, kì í ṣe èmi;ẹ̀rí tí ò ń jẹ́ nípa rẹ ní ń ta kò ọ́.

7. “Ṣé ìwọ ni ẹni kinni tí wọ́n kọ́ bí láyé?Tabi o ṣàgbà àwọn òkè?

8. Ṣé o wà ninu ìgbìmọ̀ Ọlọrun?Tabi ìwọ nìkan ni o rò pé o gbọ́n?

9. Kí ni o mọ̀, tí àwa náà kò mọ̀?Òye kí ni o ní, tí ó jẹ́ ohun ìpamọ́ fún àwa?

10. Àwọn tí wọ́n hu ewú lórí wà láàrin wa, ati àwọn àgbàlagbà,àwọn tí wọ́n dàgbà ju baba rẹ lọ.

11. Ṣé ìtùnú Ọlọrun kò tó fún ọ ni,àní ọ̀rọ̀ jẹ́ẹ́jẹ́ tí ó ń sọ fún ọ?

12. Àgbéré kí lò ń ṣe,tí o sì ń fi ojú burúkú wò wá.

13. Tí ọkàn rẹ yipada kúrò lọ́dọ̀ Ọlọrun,tí ò ń jẹ́ kí irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ ti ẹnu rẹ jáde?

14. Kí ni eniyan jẹ́, tí ó fi lè mọ́ níwájú Ọlọrun?Kí ni ẹnikẹ́ni tí obinrin bí já mọ́, tí ó fi lè jẹ́ olódodo?

15. Wò ó, Ọlọrun kò fọkàn tán àwọn angẹli,àwọn ọ̀run kò sì mọ́ níwájú rẹ̀.

16. Kí á má tilẹ̀ wá sọ ti eniyantí ó jẹ́ aláìmọ́ ati ẹlẹ́gbin,tí ń mu ẹ̀ṣẹ̀ bí ẹni mu omi!

17. “Fetí sílẹ̀, n óo sọ fún ọ,n óo sọ ohun tí ojú mi rí,

18. (ohun tí àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n sọ,tí àwọn baba wọn kò sì fi pamọ́,

19. àwọn nìkan ni a fún ní ilẹ̀ náà,àlejò kankan kò sì sí láàrin wọn).

20. Ẹni ibi ń yí ninu ìrora ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀,àní, ní gbogbo ọdún tí a là sílẹ̀ fún ìkà.

Jobu 15