Jeremaya 48:8-16 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Apanirun yóo wọ gbogbo ìlú,ìlú kankan kò sì ní bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀;àwọn àfonífojì yóo pòórá, a óo sì pa àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ run. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

9. Ẹ bá Moabu wá ìyẹ́, nítorí yóo fò bí ẹyẹ;àwọn ìlú rẹ̀ yóo di ahoro, kò ní ku ẹnikẹ́ni ninu wọn.”

10. (Ègún ń bẹ lórí ẹni tí ó bá ń fi ìmẹ́lẹ́ ṣe iṣẹ́ OLUWA;ègún sì ń bẹ lórí ẹni tí ó bá sì kọ̀, tí kò máa fi idà rẹ̀ pa eniyan.)

11. OLUWA ní,“Láti ìgbà èwe Moabu ni ó ti ń gbé pẹlu ìrọ̀rùn,kò tíì lọ sí ìgbèkùn rí.Nítorí náà ó silẹ̀ bí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ ọtí.A kò máa dà á kiri láti inú ìgò kan sí òmíràn.Adùn rẹ̀ ṣì wà lára rẹ̀, òórùn rẹ̀ kò sì tíì yipada.

12. “Nítorí náà, àkókò ń bọ̀,tí n óo jẹ́ kí wọn da Moabu nù, bí ẹni da ọtí nù.Àwọn tí wọn ń da ọtí nù ni n óo rán, tí wọn óo wá tẹ̀ ẹ́ bí ìgò ọtíwọn óo dà á nù patapata, wọn óo sì fọ́ ìgò rẹ̀.

13. Kemoṣi yóo di ohun ìtìjú fún Moabu,gẹ́gẹ́ bí Bẹtẹli, tí Israẹli gbójú lé, ṣe di ohun ìtìjú fún Israẹli.

14. Ẹ ṣe lè wí pé alágbára ni yín, ati pé ẹ jẹ́ akikanju lójú ogun?

15. Ẹni tí yóo pa ilẹ̀ Moabu ati àwọn ìlú rẹ̀ run ti dé,àwọn àṣàyàn ọmọkunrin rẹ̀ sì ti lọ sí ibi tí wọn ó ti pa wọ́n.Èmi ọba, tí orúkọ mi ń jẹ́ OLUWA àwọn ọmọ ogun, ni ó sọ bẹ́ẹ̀.

16. Ọjọ́ ìdààmú Moabu fẹ́rẹ̀ dé, ìpọ́njú rẹ̀ sì ń bọ̀ kánkán.

Jeremaya 48