Jẹnẹsisi 25:16-26 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Àwọn ni ọmọkunrin Iṣimaeli. Wọ́n jẹ́ ọba ẹ̀yà mejila, orúkọ wọn ni wọ́n sì fi ń pe àwọn ìletò ati àgọ́ wọn.

17. Iye ọdún tí Iṣimaeli gbé láyé jẹ́ ọdún mẹtadinlogoje (137). Nígbà tí ó kú a sin ín pẹlu àwọn eniyan rẹ̀.

18. Àwọn ọmọ Iṣimaeli sì ń gbé ilẹ̀ tí ó bẹ̀rẹ̀ láti Hafila títí dé Ṣuri, tí ó wà ní òdìkejì Ijipti, ní apá Asiria. Wọ́n tẹ̀dó sí òdìkejì àwọn eniyan wọn.

19. Ìran Isaaki ọmọ Abrahamu nìyí, Abrahamu ni baba Isaaki.

20. Nígbà tí Isaaki di ẹni ogoji ọdún, ó fẹ́ Rebeka. Rebeka jẹ́ ọmọ Betueli, ará Aramea, tí ń gbé Padani-aramu, ó sì tún jẹ́ arabinrin Labani, ara Aramea.

21. Isaaki gbadura sí OLUWA fún aya rẹ̀ tí ó yàgàn, OLUWA gbọ́ adura rẹ̀, Rebeka aya rẹ̀ sì lóyún.

22. Àwọn ọmọ ń ti ara wọn síhìn-ín sọ́hùn-ún ninu rẹ̀, ó sì wí pé, “Bí ó bá jẹ́ pé báyìí ni yóo máa rí, kí ni mo kúkú wà láàyè fún?” Ó bá lọ wádìí ọ̀rọ̀ náà wò lọ́dọ̀ OLUWA.

23. OLUWA wí fún un pé,“Orílẹ̀-èdè meji ni ó wà ninu rẹ,a óo sì pín àwọn oríṣìí eniyan meji tí o óo bí níyà,ọ̀kan yóo lágbára ju ekeji lọ,èyí ẹ̀gbọ́n ni yóo sì máa sin àbúrò.”

24. Nígbà tí ọjọ́ ìkúnlẹ̀ rẹ̀ pé, ìbejì ni ó bí nítòótọ́.

25. Èyí àkọ́bí pupa, gbogbo ara rẹ̀ dàbí aṣọ onírun. Nítorí náà ni wọ́n fi sọ ọ́ ní Esau.

26. Nígbà tí wọ́n bí èyí ekeji, rírọ̀ ni ó fi ọwọ́ kan rọ̀ mọ́ èyí àkọ́bí ní gìgísẹ̀. Nítorí náà ni wọ́n ṣe sọ ọ́ ní Jakọbu. Ẹni ọgọta ọdún ni Isaaki nígbà tí Rebeka bí wọn.

Jẹnẹsisi 25