Jẹnẹsisi 25:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Abrahamu fẹ́ aya mìíràn, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ketura.

2. Ketura bí Simirani, Jokiṣani, Medani, Midiani, Iṣibaku ati Ṣua fún un.

3. Jokiṣani ni baba Ṣeba ati Dedani. Àwọn ọmọ Dedani ni Aṣurimu, Letuṣimu ati Leumimu.

4. Àwọn ọmọ Midiani ni Efai, Eferi, Hanoku, Abida ati Elidaa. Àwọn ni àwọn ìran tó ṣẹ̀ lọ́dọ̀ Ketura.

5. Ṣugbọn Isaaki ni Abrahamu kó gbogbo ohun ìní rẹ̀ fún.

Jẹnẹsisi 25