Ìwé Òwe 25:8-15 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Má fi ìwàǹwára fa ẹnikẹ́ni lọ sílé ẹjọ́,nítorí kí ni o óo ṣe nígbà tí aládùúgbò rẹ bá dójútì ọ́.

9. Bí o bá ń bá aládùúgbò rẹ ṣe àríyànjiyànmá ṣe tú àṣírí ẹlòmíràn,

10. kí ẹni tí ó bá gbọ́ má baà dójútì ọ́,kí o má baà sọ ara rẹ lórúkọ.

11. Ọ̀rọ̀ tí a sọ lákòókò tí ó yẹdàbí ohun ọ̀ṣọ́ wúrà tí a gbé sinu àwo fadaka.

12. Ìbáwí ọlọ́gbọ́n dàbí òrùka wúrà,tabi ohun ọ̀ṣọ́ tí a fi wúrà ṣe,fún ẹni tí ó ní etí láti fi gbọ́.

13. Bí òtútù yìnyín nígbà ìkórè,bẹ́ẹ̀ ni olóòótọ́ iranṣẹ jẹ́, sí àwọn tí ó rán an,a máa fi ọkàn àwọn oluwa rẹ̀ balẹ̀.

14. Bí òjò tí ó ṣú dudu tí ó fẹ́ atẹ́gùn títíṣugbọn tí kò rọ̀,ni ẹni tí ó ń fọ́nnu láti fúnni lẹ́bùn,tí kò sì fúnni ní nǹkankan.

15. Pẹlu sùúrù, a lè yí aláṣẹ lọ́kàn padaọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́ sì lè fọ́ eegun.

Ìwé Òwe 25