Isikiẹli 7:11-18 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Ìwà ipá hù, ó dàgbà, ó di ọ̀pá ìwà ibi; bí ẹ ti pọ̀ tó, ẹ kò ní ṣẹ́ku ẹyọ ẹnìkan, àtẹ̀yin ati àwọn ohun ìní yín, ati ọrọ̀ yín ati ògo yín.

12. Àkókò tó; ọjọ́ náà sì ti dé tán, kí ẹni tí ń ra nǹkan má ṣe yọ̀; bẹ́ẹ̀ ni kí ẹni tí ń tà má sì banújẹ́, nítorí ibinu ti dé sórí gbogbo wọn.

13. Ẹni tí ń tà kò ní sí láyé láti pada síbi ohun tí ó tà ní ìgbà ayé ẹni tí ó rà á. Nítorí ibinu ti dé sórí gbogbo wọn. Kò sì ní yipada, bẹ́ẹ̀ ni nítorí ẹ̀ṣẹ̀ olukuluku, ẹnikẹ́ni ninu wọn kò ní sí láàyè.

14. Wọn óo fọn fèrè ogun, wọn óo múra ogun, ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò ní jáde lọ sójú ogun nítorí ibinu mi ti dé sórí gbogbo wọn.

15. Ogun ń bẹ lóde; àjàkálẹ̀-àrùn ati ìyàn wà ninu ilé. Ẹni tí ó bá wà lóko yóo kú ikú ogun. Ìyàn ati àjàkálẹ̀-àrùn yóo pa ẹni tí ó bá wà ninu ìlú.

16. Bí àwọn kan bá kù, tí wọn sá àsálà, wọn yóo dàbí àdàbà àfonífojì lórí àwọn òkè. Gbogbo wọn yóo máa sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn olukuluku yóo máa dárò nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

17. Ọwọ́ gbogbo wọ́n yóo rọ; orúnkún wọn kò ní lágbára.

18. Wọn óo wọ aṣọ ọ̀fọ̀, ìpayà óo sì bá wọn. Ojú óo ti gbogbo wọn; gbogbo wọn óo sì di apárí.

Isikiẹli 7