Isikiẹli 5:9-12 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Nítorí gbogbo ìwà ìríra yín, n óo ṣe ohun tí n kò ṣe rí si yín, tí n kò sì ní ṣe irú rẹ̀ mọ́ lae.

10. Baba yóo máa pa ọmọ wọn jẹ láàrin yín; ọmọ yóo sì máa pa àwọn baba jẹ. N óo dájọ́ fun yín, n óo fọ́n gbogbo àwọn tí ó kù ninu yín káàkiri igun mẹrẹẹrin ayé.

11. “Bí mo ti wà láàyè, n óo pa yín run. N kò ní fojú fo ohunkohun, n kò sì ní ṣàánú yín rárá; nítorí ẹ ti fi àwọn nǹkan ẹ̀sìn ìríra ati àṣà burúkú yín sọ ilé mímọ́ mi di aláìmọ́.

12. Àjàkálẹ̀ àrùn ati ìyàn yóo pa ìdámẹ́ta lára yín, ogun tí yóo máa jà káàkiri yóo pa ìdámẹ́ta yín, n óo fọ́n ìdámẹ́ta yòókù káàkiri gbogbo ayé, n óo sì gbógun tì wọ́n.

Isikiẹli 5