Ìṣe Àwọn Aposteli 8:4-14 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Àwọn tí wọ́n túká bá ń lọ káàkiri, wọ́n ń waasu ọ̀rọ̀ náà.

5. Filipi lọ sí ìlú Samaria kan, ó waasu fún wọn nípa Kristi.

6. Àwọn eniyan ṣù bo Filipi kí wọ́n lè gbọ́ ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ, wọ́n sì ń rí iṣẹ́ abàmì tí ó ń ṣe.

7. Nítorí àwọn ẹ̀mí burúkú ń lọgun bí wọ́n ti ń jáde kúrò ninu ọpọlọpọ eniyan. Bẹ́ẹ̀ ni a mú ọpọlọpọ àwọn arọ ati àwọn tí wọ́n ní àbùkù ara lára dá.

8. Inú àwọn eniyan dùn pupọ ní ìlú náà.

9. Ọkunrin kán wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Simoni, tí ó ti máa ń pidán ní ìlú náà. Èyí jẹ́ ìyanu fún àwọn ará Samaria, wọ́n ní ẹni ńlá ni ọkunrin náà.

10. Gbogbo eniyan ló kà á kún; ati àwọn eniyan yẹpẹrẹ ati àwọn eniyan pataki wọn. Wọ́n ní, “Eléyìí ní agbára Ọlọrun tí à ń pè ní ‘Agbára ńlá.’ ”

11. Tẹ́lẹ̀ rí òun ni àwọn eniyan kà kún, tí idán tí ó ń pa ń yà wọ́n lẹ́nu.

12. Ṣugbọn nígbà tí wọ́n gba ìyìn rere tí Filipi waasu nípa ìjọba Ọlọrun ati orúkọ Jesu Kristi gbọ́, tọkunrin tobinrin wọn ṣe ìrìbọmi.

13. Simoni náà gbàgbọ́, ó ṣe ìrìbọmi, ni ó bá fara mọ́ Filipi. Nígbà tí ó rí iṣẹ́ abàmì ati iṣẹ́ ìyanu ńlá tí ó ń ṣe, ẹnu yà á.

14. Àwọn aposteli tí ó wà ní Jerusalẹmu gbọ́ bí àwọn ará Samaria ti gba ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Wọ́n bá rán Peteru ati Johanu sí wọn.

Ìṣe Àwọn Aposteli 8