Ìṣe Àwọn Aposteli 17:20-28 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Nítorí ohun tí ò ń sọ ṣe àjèjì létí wa. A sì fẹ́ mọ ìtumọ̀ rẹ̀.”

21. (Gbogbo àwọn ará Atẹni ní tiwọn, ati àwọn àlejò tí ó ń gbé ibẹ̀, kí wọn ṣá máa ròyìn nǹkan titun tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ wọ̀lú ni iṣẹ́ tiwọn. Bí wọn bá ti gbọ́ èyí, ohun tí ó ń ṣe wọ́n tán.)

22. Paulu bá dìde dúró láàrin ìgbìmọ̀ tí ó wà ní Òkè Areopagu, ó ní, “Ẹ̀yin ará Atẹni, ó hàn lọ́tùn-ún lósì sí ẹni tí ó bá wò ó pé ẹ kò fi ọ̀rọ̀ oriṣa ṣeré.

23. Bí mo ti ń lọ tí mò ń bọ̀ ni mò ń fojú wo àwọn ohun tí ẹ̀ ń sìn. Mo rí pẹpẹ ìrúbọ kan tí ẹ kọ àkọlé báyìí sí ara rẹ̀ pé: ‘Sí Ọlọrun tí ẹnìkan kò mọ̀.’ Ohun tí ẹ kò mọ̀ tí ẹ̀ ń sìn, òun ni mò ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ fun yín.

24. Ọlọrun tí ó dá ayé ati gbogbo nǹkan tí ó wà ninu rẹ̀, Oluwa ọ̀run ati ayé, kì í gbé ilé oriṣa àfọwọ́kọ́;

25. bẹ́ẹ̀ ni kò sí ohun tí kò ní, tí a óo sọ pé kí eniyan fún un, nítorí òun fúnra rẹ̀ ni ó ń fún gbogbo eniyan ní ẹ̀mí, èémí ati ohun gbogbo.

26. Òun ni ó dá gbogbo orílẹ̀-èdè láti inú ẹnìkan ṣoṣo láti máa gbé gbogbo ilẹ̀ ayé. Kí ó tó dá wọn, ó ti ṣe ìpinnu tẹ́lẹ̀ nípa ìgbà tí wọn yóo gbé ní ayé ati ààlà ibi tí wọn yóo máa gbé.

27. Ó dá wọn láti máa wá òun Ọlọrun, bí ó bá ṣeéṣe, kí wọ́n fọwọ́ kàn án, kí wọ́n rí i. Kò sì kúkú jìnnà sí ẹnìkan kan ninu wa.

28. Nítorí ẹnìkan sọ níbìkan pé:‘Ninu rẹ̀ ni à ń gbé,tí à ń rìn kiri,tí a wà láàyè.’Àwọn kan ninu àwọn akéwì yín pàápàá ti sọ ohun tó jọ bẹ́ẹ̀; wọ́n ní,‘Ọmọ rẹ̀ ni a jẹ́.’

Ìṣe Àwọn Aposteli 17