12. Hamani tún fi kún un pé “Ayaba Ẹsita kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni bá ọba wá sí ibi àsè rẹ̀, àfi èmi nìkan. Ó sì ti tún pe èmi ati ọba sí àsè mìíràn ní ọ̀la.
13. Ṣugbọn gbogbo nǹkan wọnyi kò lè tẹ́ mi lọ́rùn, bí mo bá ń rí Modekai, Juu, tí ó ń jókòó ní ẹnu ọ̀nà ààfin ọba.”
14. Sereṣi iyawo rẹ̀ ati àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ fún un, pé, “Lọ ri igi tí wọn ń gbé eniyan kọ́, kí ó ga ní ìwọ̀n aadọta igbọnwọ. Bí ilẹ̀ bá ti mọ́, sọ fún ọba pé kí ó so Modekai kọ́ sí orí igi náà. Nígbà náà inú rẹ yóo dùn láti lọ sí ibi àsè náà.” Inú Hamani dùn sí ìmọ̀ràn yìí, ó lọ ri igi náà mọ́lẹ̀.