Ẹsira 7:6-11 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Láti Babiloni ni Ẹsira tí à ń wí yìí ti dé. Akọ̀wé ni, ó sì já fáfá ninu òfin Mose, tí OLUWA Ọlọrun Israẹli fún wọn. Ọba fún un ní gbogbo nǹkan tí ó bèèrè, nítorí pé ó rí ojurere OLUWA Ọlọrun rẹ̀.

7. Ní ọdún keje ìjọba Atasasesi, díẹ̀ ninu àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n ti ìgbèkùn dé: àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi, àwọn akọrin, àwọn aṣọ́nà ati àwọn iranṣẹ ninu Tẹmpili,

8. wá sí Jerusalẹmu. Ní oṣù karun-un ọdún keje ìjọba Atasasesi ni Ẹsira dé sí Jerusalẹmu.

9. Ó bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò rẹ̀ láti Babiloni ní ọjọ́ kinni oṣù kinni, ó sì dé Jerusalẹmu ní ọjọ́ kinni oṣù karun-un nítorí pé ó rí ojurere Ọlọrun.

10. Nítorí Ẹsira fi gbogbo ọkàn rẹ̀ sí kíkọ́ òfin OLUWA, ati pípa á mọ́ ati kíkọ́ gbogbo àwọn ọmọ Israẹli.

11. Ohun tí wọ́n kọ sinu ìwé tí ọba Atasasesi fún Ẹsira nìyí,

Ẹsira 7