Daniẹli 5:20-28 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Ṣugbọn nígbà tí ó gbé ara rẹ̀ ga, tí ó sì ṣe oríkunkun, a mú un kúrò lórí ìtẹ́ rẹ̀, a sì mú ògo rẹ̀ kúrò.

21. A lé e kúrò láàrin àwọn ọmọ eniyan, ọkàn rẹ̀ dàbí ti ẹranko. Ó ń bá àwọn ẹranko gbé inú igbó. Ó ń jẹ koríko bíi mààlúù, ìrì sì sẹ̀ sí i lára, títí ó fi mọ̀ pé Ọlọrun tí ó ga jùlọ, ni ó ní àṣẹ lórí ìjọba eniyan, tí ó sì ń gbé e fún ẹni tí ó bá wù ú.

22. “Bẹ́ẹ̀ ni, ìwọ ọmọ rẹ̀ Beṣasari, o kọ̀, o kò rẹ ara rẹ sílẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o mọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí.

23. Ò ń gbéraga sí Ọlọrun ọ̀run. O ranṣẹ lọ kó àwọn ohun èlò ilé Ọlọrun wá siwaju rẹ. Ìwọ ati àwọn ìjòyè rẹ, àwọn ayaba ati àwọn obinrin rẹ, ẹ bẹ̀rẹ̀ sí fi wọ́n mu ọtí waini. Ẹ sì ń yin àwọn oriṣa fadaka, ti wúrà, ti idẹ, ti irin, ti igi ati ti òkúta. Wọn kò ríran wọn kò gbọ́ràn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò mọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀. O kò yin Ọlọrun tí ẹ̀mí rẹ wà lọ́wọ́ rẹ̀ lógo, ẹni tí ó mọ gbogbo ọ̀nà rẹ.

24. Ìdí nìyí tí ó fi rán ọwọ́ kan jáde láti kọ àkọsílẹ̀ yìí.

25. “Ohun tí a kọ náà nìyí: ‘MENE, MENE, TEKELI, PERESINI.’

26. Ìtumọ̀ rẹ̀ sì nìyí: MENE, Ọlọrun ti ṣírò àwọn ọjọ́ ìjọba rẹ, ó sì ti parí rẹ̀.

27. TEKELI, a ti wọ̀n ọ́ lórí ìwọ̀n, o kò sì kún ojú ìwọ̀n.

28. PERESINI, a ti pín ìjọba rẹ, a sì ti fún àwọn ará Mede ati àwọn ará Pasia.”

Daniẹli 5