Àwọn Ọba Kinni 11:6-17 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Ohun tí Solomoni ṣe burú lójú OLUWA, kò sì jẹ́ olóòótọ́ sí i gẹ́gẹ́ bí Dafidi, baba rẹ̀.

7. Ó kọ́ pẹpẹ ìrúbọ kan sí orí òkè ní ìhà ìlà oòrùn Jerusalẹmu fún oriṣa Kemoṣi, ohun ìríra tí àwọn ará Moabu ń bọ, ati fún oriṣa Moleki, ohun ìríra tí àwọn ará Amoni ń bọ.

8. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe fún gbogbo àwọn iyawo àjèjì tí ó fẹ́, tí wọn ń sun turari, tí wọ́n sì ń rúbọ sí àwọn oriṣa wọn.

9. Inú bí OLUWA sí Solomoni, nítorí pé, ọkàn rẹ̀ ti yipada kúrò lọ́dọ̀ OLUWA Ọlọrun Israẹli tí ó fara hàn án nígbà meji,

10. tí ó sì pàṣẹ fún un nítorí ọ̀rọ̀ yìí pé kò gbọdọ̀ bọ oriṣa. Ṣugbọn kò pa òfin OLUWA mọ́.

11. OLUWA bá sọ fún Solomoni pé, “Nítorí pé o ti ṣe ìfẹ́ ọkàn rẹ, o kò pa majẹmu mi mọ́, o kò sì tẹ̀lé ìlànà tí mo pa láṣẹ fún ọ, dájúdájú n óo gba ìjọba náà kúrò ní ọwọ́ rẹ, n óo sì fi fún ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹ rẹ.

12. Ṣugbọn nítorí ti Dafidi baba rẹ, n kò ní ṣe ohun tí mo fẹ́ ṣe yìí ní àkókò tìrẹ. Ọmọ rẹ ni n óo já ìjọba gbà mọ́ lọ́wọ́.

13. Ṣugbọn n kò ní gba gbogbo ìjọba náà kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, n óo ṣẹ́ ẹ̀yà kan kù sí ọmọ rẹ lọ́wọ́, nítorí ti Dafidi iranṣẹ mi ati ìlú Jerusalẹmu tí mo ti yàn.”

14. OLUWA bá mú kí Adadi dojú ọ̀tá kọ Solomoni; Adadi yìí jẹ́ ìran ọba ní ilẹ̀ àwọn ará Edomu.

15. Ṣáájú àkókò yìí, nígbà tí Dafidi gbógun ti àwọn ará Edomu, tí ó sì ṣẹgun wọn, Joabu balogun rẹ̀ lọ sin àwọn tí wọ́n kú sógun, ó sì pa gbogbo àwọn ọmọkunrin Edomu;

16. nítorí pé Joabu ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀ wà ní ilẹ̀ Edomu fún oṣù mẹfa, títí tí ó fi pa gbogbo àwọn ọkunrin tí wọ́n wà ní ilẹ̀ Edomu run.

17. Ṣugbọn Adadi ati díẹ̀ lára àwọn iranṣẹ baba rẹ̀, tí wọ́n jẹ́ ará Edomu sá lọ sí ilẹ̀ Ijipti, Adadi kéré pupọ nígbà náà.

Àwọn Ọba Kinni 11