Àwọn Ọba Keji 14:26-29 BIBELI MIMỌ (BM)

26. OLUWA rí i pé ìpọ́njú àwọn ọmọ Israẹli pọ̀, kò sì sí ẹni tí ìpọ́njú náà kò kàn, ati ẹrú ati ọmọ, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí ó lè ràn wọ́n lọ́wọ́.

27. Bẹ́ẹ̀ sì ni OLUWA kò tíì sọ pé òun óo pa gbogbo Israẹli run, nítorí náà, ó ṣẹgun fún wọn láti ọwọ́ Jeroboamu ọmọ Jehoaṣi.

28. Gbogbo nǹkan yòókù tí Jeroboamu ṣe, ìwà akọni rẹ̀ lójú ogun ati bí ó ti gba Damasku ati Hamati, tí wọ́n jẹ́ ti Juda tẹ́lẹ̀ rí, fún Israẹli, gbogbo rẹ̀ ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Israẹli.

29. Jeroboamu kú, wọ́n sin òkú rẹ̀ sinu ibojì àwọn ọba, Sakaraya, ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.

Àwọn Ọba Keji 14