Aisaya 63:6-15 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Mo fi ibinu tẹ àwọn orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀,mo fi ìrúnú rọ wọ́n yó,mo sì tú ẹ̀jẹ̀ wọn dà sílẹ̀.”

7. N óo máa sọ nípa ìfẹ́ ńlá OLUWA lemọ́lemọ́,n óo máa kọrin ìyìn rẹ̀;nítorí gbogbo ohun tí OLUWA ti fún wa,ati oore ńlá tí ó ṣe fún ilé Israẹli,tí ó ṣe fún wọn nítorí àánú rẹ̀,ati gẹ́gẹ́ bí ọpọlọpọ ìfẹ́ rẹ̀ tí kìí yẹ̀.

8. OLUWA ní, “Dájúdájú eniyan mi mà ni wọ́n,àwọn ọmọ tí kò ní hùwà àgàbàgebè.”Ó sì di Olùgbàlà wọn.

9. Ninu gbogbo ìyà tí wọ́n jẹ, òun pẹlu wọn ni,angẹli iwájú rẹ̀ sì gbà wọ́n là.Nítorí ìfẹ́ ati àánú rẹ̀, ó rà wọ́n pada.Ó fà wọ́n sókè, ó sì gbé wọn ní gbogbo ìgbà àtijọ́.

10. Ṣugbọn wọ́n hùwà ọlọ̀tẹ̀:wọ́n sì mú Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ bínú.Nítorí náà ó di ọ̀tá wọn,ó sì dojú ìjà kọ wọ́n.

11. Ṣugbọn ó ranti ìgbà àtijọ́,ní àkókò Mose, iranṣẹ rẹ̀.Wọ́n bèèrè pé,ẹni tí ó kó wọn la òkun já dà?Olùṣọ́-aguntan agbo rẹ̀,tí ó fi Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀ sáàrin wọn?

12. Ẹni tí ó gbé agbára rẹ̀ tí ó lógo wọ Mose,tí ó pín òkun níyà níwájú wọn,kí orúkọ rẹ̀ lè lókìkí títí lae.

13. Ó mú wọn la ibú omi kọjá, bí ẹṣin ninu aṣálẹ̀;wọ́n rìn, wọn kò fẹsẹ̀ kọ.

14. Wọ́n rìn wọnú àfonífojì bíi mààlúù,Ẹ̀mí OLUWA sì fún wọn ní ìsinmi.Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe darí àwọn eniyan rẹ̀,kí ó lè gba ògo fún orúkọ rẹ̀.

15. Bojúwo ilẹ̀ láti ọ̀run,láti ibùgbé rẹ mímọ́ tí ó lógo.Ìtara rẹ dà? Agbára rẹ dà?O ti dáwọ́ ìfẹ́ ati àánú rẹ dúró lára wa ni?

Aisaya 63