1. Ní ọdún kẹrinla tí Ọba Hesekaya jọba, Senakeribu, ọba Asiria gbógun ti gbogbo ìlú olódi Juda, ó sì kó wọn.
2. Ọba Asiria rán Rabuṣake (olórí ogun rẹ̀), pẹlu ọpọlọpọ ọmọ ogun; láti Lakiṣi sí ọba Hesekaya ní Jerusalẹmu. Nígbà tí wọn dé ibi tí omi tí ń ṣàn wọ ìlú láti orí òkè tí ó wà ní ọ̀nà pápá alágbàfọ̀, wọ́n dúró níbẹ̀.
3. Eliakimu, ọmọ Hilikaya tí ó jẹ́ alákòóso ààfin jáde lọ bá wọn pẹlu Ṣebina, akọ̀wé ilé ẹjọ́, ati Joa ọmọ Asafu, akọ̀wé ààfin.
4. Rabuṣake bá sọ fún wọn pé, “Ẹ sọ fún Hesekaya pé ọba ńlá Asiria ní kí ló gbójú lé rí?
5. Ó ní ṣé Hesekaya rò pé ọ̀rọ̀ ẹnu ni ọgbọ́n ati agbára tí wọ́n fi ń jagun ni; àbí ta ló gbójú lé tí ó fi ń ṣàìgbọràn sí òun?
6. Ó ní Ijipti tí Hesekaya gbára lé dàbí kí eniyan fi ìyè ṣe ọ̀pá ìtẹ̀lẹ̀, ìyè tí yóo dá, tí yóo sì gún ẹnikẹ́ni tí ó bá gbára lé e lọ́wọ́. Bẹ́ẹ̀ ni Farao ọba Ijipti jẹ́ sí gbogbo àwọn tí ó bá gbára lé e.
7. “Ó ní bí Hesekaya bá sì sọ fún òun pé, OLUWA Ọlọrun àwọn ni àwọn gbójú lé, òun óo bi í pé, ṣé kì í ṣe ojúbọ OLUWA náà ati àwọn pẹpẹ ìrúbọ rẹ̀ ni Hesekaya wó lulẹ̀ nígbà tí ó sọ fún àwọn ará Juda ati àwọn ará Jerusalẹmu pé, ẹyọ pẹpẹ kan ni kí wọ́n ti máa sin OLUWA?”