9. Ilẹ̀ ṣófo ó sì gbẹ,ìtìjú bá òkè Lẹbanoni,gbogbo ewéko orí rẹ̀ sì rẹ̀ dànù.Ṣaroni dàbí aṣálẹ̀,igi igbó Baṣani ati ti òkè Kamẹli sì wọ́wé.
10. OLUWA ní:“Ó yá tí n óo dìde,ó yá mi wàyí, n óo gbéra nílẹ̀.Àsìkò tó tí a óo gbé mi ga.
11. Èrò yín dàbí fùlùfúlù, gbogbo ìṣe yín dàbí pòpórò ọkà.Èémí mi yóo jó yín run bí iná.
12. Àwọn orílẹ̀-èdè yóo dàbí ìgbà tí a sun wọ́n,tí wọ́n di eérú,àní bí igi ẹ̀gún tí a gé lulẹ̀, tí a sì dáná sun.