1. Rán àwọn ènìyàn náà létí láti máa tẹríba fún ìjọba àti àwọn aláṣẹ. Kí wọn ṣe ìgbọ́ràn nígbà gbogbo, kí wọn sì múra fún iṣẹ́ rere gbogbo.
2. Wọn kò gbọdọ̀ sọ̀rọ̀ ẹnikẹ́ni ní ibi, kí wọn jẹ́ ẹni àlááfíà àti ẹni pípé, kí wọn sì máa gbé ìgbé-ayé ìwà tútù pẹ̀lú ènìyàn gbogbo.
3. Nígbà kan rí, àwa pàápàá jẹ́ opè àti aláìgbọ́ràn, àti tàn wá jẹ, a sè ti sọ wá di ẹrú fún onírúurú ìfẹ́kùfẹ̀ẹ́ àti adùn ayé. À ń gbé ìgbé-ayé àrankan àti owú kíkorò, a jẹ́ ẹni ìríra, a sì ń kórira ọmọ ẹnìkejì wa pẹ̀lú.
4. Ṣùgbọ́n nígbà tí inú rere àti ìfẹ́ Ọlọ́run Olùgbàlà wa farahàn,
5. Ó gbà wá là. Kì í ṣe nípa iṣẹ́ tí àwa ṣe nínú òdodo bí kò ṣe nítorí àánú rẹ̀. Ó gbà wá là, nípaṣẹ̀ ìwẹ̀nù àtúnbí àti ìsọdọ̀tun ti Ẹ̀mí Mímọ́,
6. èyí tí tú lé wa lórí ní ẹ̀kún-rẹ́rẹ́ nípaṣẹ̀ Jésù Kírísítì Olùgbàlà wá.