Sekaráyà 12:11-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Ní ọjọ́ náà ni ẹkún, ńláńlá yóò wà ni Jérúsálẹ́mù, gẹ́gẹ́ bí ọ̀fọ̀ Hádádì Rímónì ni àfonífojì Mégídónì.

12. Ilẹ̀ náà yóò ṣọ̀fọ̀, ìdílé, ìdílé, lọ́tọ̀ọ̀tọ̀; ìdílé Dáfídì lọ́tọ̀; àti àwọn aya wọn lọ́tọ̀; ìdílé Nátanì lọ́tọ̀, àti àwọn aya wọn lọ́tọ́.

13. Ìdílé Léfì lọ́tọ̀, àti àwọn aya wọn lọ́tọ̀; ìdílé Ṣimei lọ́tọ̀, àti àwọn aya wọn lọ́tọ̀.

14. Gbogbo àwọn ìdílé tí o kù, ìdílé, ìdílé, lọ́tọ̀ọ̀tọ̀, àti àwọn aya wọn lọ́tọ̀.

Sekaráyà 12