Sefanáyà 3:12-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Ṣùgbọ́n Èmi yóò fi àwọn ọlọ́kàn tútùàti onírẹ̀lẹ̀ sílẹ̀ pẹ̀lú ni àárin rẹ̀,wọn yóò sì gbẹ́kẹ̀lé orúkọ Olúwa.

13. Àwọn ìyókù Ísírẹ́lì kì yóò hùwàibi, wọn kì yóò sọ̀rọ̀ èké,bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò rí ahọ́n àrékérekè níẹnu wọn. Àwọn yóò jẹun, wọn yóò sì dùbúlẹ̀,bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kì yóò dẹ́rù bà wọ́n.”

14. Kọrin, ìwọ ọmọbìnrin Síónì,kígbé sókè, ìwọ Ísírẹ́lì!Fi gbogbo ọkàn yọ̀, kí inú rẹ kí ó sì dùn,ìwọ ọmọbìnrin Jérúsálẹ́mù.

15. Olúwa ti mú ìdájọ́ rẹ wọ̀n-ọn-nìkúrò, ó sì ti ti àwọn ọ̀ta rẹ padà sẹ́yìn. Olúwa, ọba Ísírẹ́lì wà pẹ̀lú rẹ,Ìwọ kì yóò sì bẹ̀rù ibi kan mọ́.

Sefanáyà 3