1. Ègbé ni fún ìlú aninilára,ọlọ̀tẹ̀ àti aláìmọ́.
2. Òun kò gbọ́ràn sí ẹnikẹ́ni,òun kò gba ìtọ́ni,òun kò gbẹ́kẹ̀lé Olúwa,bẹ́ẹ̀ ni òun kò súnmọ́ ọ̀dọ̀ Ọlọ́run rẹ̀.
3. Àwọn olórí rẹ̀ jẹ́ kìnnìun tí ń ké ramúramù,àwọn onídàájọ́ rẹ̀, ìkokò àṣálẹ́ ni wọn,wọn kò sì fi nǹkan kan kalẹ̀ fún òwúrọ̀.
4. Àwọn wòlíì rẹ̀ gbéraga,wọ́n sì jẹ́ alárékérekè ènìyàn.Àwọn àlùfáà rẹ̀ ti ba ibi mímọ́ jẹ́,wọ́n sì rú òfin.
5. Olúwa ni àárin rẹ̀ jẹ́ olódodo;kì yóò ṣe ohun tí kò tọ̀nà.Àràárọ̀ ni ó máa ń mú ìdájọ́ rẹ̀ wá sí ìmọ́lẹ̀,kì í sì kùnà ní gbogbo ọjọ́ tuntun,ṣíbẹ̀ àwọn aláìsòótọ́ kò mọ ìtìjú.
6. “Èmi ti ké àwọn orílẹ̀-èdè kúrò,ilé gíga wọn sì ti bàjẹ́.Mo ti fi ìgboro wọn sílẹ̀ ní ihàtóbẹ́ẹ̀ tí ẹnìkan kan kò kọjá níbẹ̀.Ìlú wọn parun tóbẹ́ẹ̀ tí kò síẹnikan tí yóò sẹ́kù,kò sì ní sí ẹnìkan rárá.
7. Èmi wí fún ìlú náà wí pé‘Nítòótọ́, ìwọ yóò bẹ̀rù mi,ìwọ yóò sì gba ìtọ́ni!’Bẹ́ẹ̀ ni, a kì yóò ké ibùgbé rẹ̀ kúròbí ó ti wù kí ń jẹ wọ́n níyà tó.Ṣùgbọ́n ṣíbẹ̀ wọ́n sì tún ní ìtaraláti ba iṣẹ́ wọn jẹ́.