Sefanáyà 2:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ kó ara yín jọ pọ̀, àní ẹ kó ra yín jọpọ̀orílẹ̀ èdè tí kò ní ìtìjú,

2. kí a tó lé yín kúrò bí èrò ìyàngbò ọkà,kí gbígbóná ìbínú Olúwa tó dé bá a yín, kíọjọ́ ìbínú Olúwa kí ó tó dé bá a yín.

3. Ẹ wá Olúwa, gbogbo ẹ̀yin onírẹ̀lẹ̀ ilẹ̀ náà,ẹ̀yin tí ń ṣe ohun tí ó bá pa láṣẹ.Ẹ wá òdodo, ẹ wá ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú,bóyá á ó pa yín mọ́ ní ọjọ́ ìbínú Olúwa.

4. Nítorí pé, a ó kọ Gásà sílẹ̀,Áṣíkélónì yóò sì dahoro.Ní ọ̀sán gangan ni a ó lé Áṣídódù jáde,a ó sì fa Ékírónì tu kúrò.

Sefanáyà 2