Sáàmù 93:2-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Ìjọba Rẹ̀ wà láti ọjọ́ pípẹ́;ìwọ wà títí ayé raye.

3. A ti gbé òkun sókè, Olúwa,òkun ti gbé ohùn wọn sókè;òkun ti gbé rírú omi wọn sókè.

4. Ó ni ògo ju àrá omi ńlá lọ,ó ni ògo ju òkun rírú lọ Olúwa ga ní ògo.

5. Ẹ̀rí Rẹ̀ dúró ṣinṣin;ìwà mímọ́ ni ó fi ṣe ilé Rẹ̀ lọ́sọ̀ọ́fún ọjọ́ àìlópin, Olúwa.

Sáàmù 93