Sáàmù 89:25-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Èmi o gbé ọwọ́ Rẹ lórí òkunàti ọwọ́ ọ̀tún Rẹ lórí àwọn odo ńlá

26. Òun yóò kígbe sí mi pé, ‘ìwọ ní bàbá mi, Ọlọ́run mi, àti àpáta ìgbàlà mi!’

27. Èmi yóò ṣe é ni àkọ́bí mí,Ẹni gíga jù àwọn ọba ayé.

28. Títí láé ni èmi yóò pa ìfẹ́ dídúró ṣinṣin mọ́ fún un,àti májẹ̀mú mi pẹ̀lú Rẹ̀ yóò dúró gbọingbọin.

29. Èmi o fi ìdí irú ọmọ Rẹ̀ múlẹ̀ títí láé,àti ìtẹ́ Rẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti wà láé.

Sáàmù 89