Sáàmù 85:7-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Fi ìfẹ́ Rẹ tí kò le e kùnà hàn wá, Olúwa,Kí o sì fún wa ní ìgbàlà Rẹ.

8. Èmi ó gbọ́ ohun tí Olúwa Ọlọ́run yóò wí;ó ṣèlérí àlàáfíà fún àwọn ènìyàn Rẹ̀, àní ẹni mímọ́ Rẹ̀:Ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí wọn padà sí àìmòye.

9. Nítòótọ́ ìgbàlà Rẹ̀ súnmọ́ àwọn tí ó bẹ̀rù Rẹ̀,pé kí ògo Rẹ̀ kí ó le gbé ní ilẹ̀ wa.

10. Ìfẹ́ àti òtítọ́ parapọ̀;òdodo àti àlàáfíà fẹnu ko ara wọn.

11. Òtítọ́ ń sun jáde láti ilẹ̀ wáòdodo sì bojúwolẹ̀ láti ọ̀run.

12. Olúwa yóò fi ohun dídára fún ni nítòótọ́,ilẹ̀ wa yóò sì mú ìkórè Rẹ̀ jáde.

13. Òdodo ṣíwájú Rẹ lọo sì pèṣè ọ̀nà fún ìgbésẹ̀ Rẹ̀.

Sáàmù 85