1. Ọlọ́run, Má ṣe dákẹ́;Má ṣe dákẹ́, Ọlọ́run má ṣe dúró jẹ́ ẹ́.
2. Wo bí àwọn ọ̀tá Rẹ ti ń rọ́kẹ̀kẹ̀ lọ,bi àwọn ọ̀tá Rẹ ti ń gbé ohùn wọn sókè.
3. Pẹ̀lú àrékérekè ni wọn dìtẹ̀ sí àwọn ènìyàn Rẹ;wọn gbìmọ̀ lòdì sí àwọn tí ó fẹ.
4. Wọn wí pé, “wá,” ẹ jẹ́ kí a pa wọn run bí orílẹ̀ èdè,kí orúkọ Ísírẹ́lì ma bá a sí ní ìrántí mọ́.
5. Wọn gbìmọ̀ pọ̀ pẹ̀lú ọkàn kan;wọ́n ṣe àdéhùn láti ṣọ̀tẹ̀ sí ọ