Sáàmù 80:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Gbọ́ tiwa, ìwọ olùsọ́ àgùntàn Ísírẹ́lì;ìwọ tí ó darí Jósẹ́fù bí ọwọ́ ẹran;ìwọ tí o jòkòó lórí ìtẹ́ láàrin Kérúbù, tàn jáde

2. Níwájú Éfúremù, Bẹ́ńjámínì àti Mánásè.Rú agbára Rẹ̀ sókè;wa fún ìgbàlà wa.

3. Mú wa padà bọ̀ sípò, ìwọ Ọlọ́run;jẹ́ kí ojú Rẹ kí ó tan ìmọ́lẹ̀ sí wa,kí a bà lé gbà wá là

4. Olúwa Ọlọ́run,ìbínú Rẹ̀ yóò ti pẹ́ tósí àdúrà àwọn ènìyàn Rẹ?

Sáàmù 80