1. Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ gbọ́ ẹ̀kọ́ mi;tẹ́tí Rẹ sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi.
2. Èmi ó la ẹnu mi ní òweèmi o sọ ohun ìkọ̀kọ̀, ohun ti ọjọ́ pípẹ́;
3. Ohun tí a ti gbọ́ tí a sì ti mọ̀,ohun tí àwọn baba wa ti sọ fún wa.
4. Àwa kí yóò pa wọ́n mọ́kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ,ní fífí ìyìn Olúwa, àti ipa Rẹ̀àti iṣẹ́ ìyanu tó ti ṣe hànfún ìran tí ń bọ̀.
5. Ó gbé ẹ̀rí kalẹ̀ ní Jákọ́bùo sì fìdí àṣẹ múlẹ̀ ní Ísírẹ́lì,èyí tí ó páláṣẹ fún àwọn baba ńlá waláti kọ́ àwọn ọmọ wọn,