Sáàmù 75:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. A fi ìyìn fún ọ, Ọlọ́run,a yìn ọ́, nítorí orúkọ Rẹ̀ súnmọ́ tòsí;àwọn ènìyàn ń sọ ti ìyanu Rẹ.

2. Ìwọ wí pé, “Mo yan àkókò ìyàsọ́tọ̀;Èmi ni ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ òdodo.

3. Nígbà tí ayé àti àwọn ènìyàn ibẹ̀ wárìrì,Èmi ni mo di òpó Rẹ̀ mú ṣinṣin.

4. Èmí wí fún àwọn agbéraga péẸ má ṣe gbéraga mọ́;àti sí ènìyàn búburú;Ẹ má ṣe gbé ìwo yín sókè.

Sáàmù 75