Sáàmù 69:8-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Mo jẹ́ àjèjì si àwọn arákùnrin mi;àlejò sí àwọn arákùnrin ìyá mi;

9. Nítorí ìtarà ilé Rẹ jẹ mí run,àti ẹ̀gàn àwọn tí ń gàn ọ́ ṣubú lù mí.

10. Nígbà tí mo sunkúntí mo sì ń fi ààwẹ̀ jẹ ara mi ní ìyàèyí náà sì dín ẹ̀gàn mi kù;

11. Nígbà tí mo wọ aṣọ àkísà,àwọn ènìyàn ń pòwe mọ́ mi.

12. Àwọn tí ó jòkòó ní ẹnu ibodè ń bú mi,mo sì di orin àwọn ọ̀mùtí.

13. Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi niìwọ ni èmi n gbàdúrà mi sí Olúwa,ní ìgbà ìtẹ́wọ́gbàỌlọ́run, nínú ìfẹ́ títóbi Rẹ,dá mí lóhùn pẹ̀lú ìgbàlà Rẹ tí ó dájú.

14. Gbá mí kúrò nínú ẹrẹ̀,Má ṣe jẹ́ kí ń rí;gbà mí lọ́wọ́ àwọn tí o korìíra mi,kúrò nínú ibú omi.

15. Má ṣe jẹ́ kí ìkún omi bò mí mọ́lẹ̀bẹ́ẹ̀ ni má ṣe jẹ́ kí ọ̀gbìn gbé mi mìkí o má sì ṣe jẹ́ kí ihò pa ẹnu Rẹ̀ dé mọ́ mi.

16. Dá mí lóhùn, Olúwa nínú ìṣeun ìfẹ́ Rẹ;nínú ọ̀pọ̀ àánú Rẹ yípadà sí mi.

17. Má ṣe pa ojú Rẹ mọ́ fún ọmọ ọ̀dọ̀ Rẹ:yára dá mi lóhùn, nítorí mo wà nínú ìpọ́njú.

18. Súnmọ́ tòsí kí ó sì gbà mí là;rà mí padà nítorí àwọn ọ̀ta mi.

19. Ìwọ tí mọ ẹ̀gàn mi, ìtìjú mi àti àìlọ́lá;Gbogbo àwọn ọ̀ta mi wà níwájú Rẹ̀.

20. Ẹ̀gàn ba ọkàn mi jẹ́ wọ́n fi mí sílẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́Mo ń wá aláàánú, ṣùgbọ́n kò sí,mo ń wá olùtùnú, Ṣùgbọ́n n kò rí ẹnìkankan.

Sáàmù 69