5. Ẹ wá wo ohun tí Ọlọ́run ṣe,Iṣẹ́ Rẹ̀ ti ní ẹ̀rù tó sí àwọn ọmọ ènìyàn!
6. O yí òkun padà sí ilẹ̀ gbígbẹ,wọ́n fi ẹsẹ̀ rìn inú omi kọjá,níbẹ̀ ni àwa yọ̀ nínú Rẹ.
7. O ń jọba títí láé nípa agbára Rẹ̀,ojú Rẹ̀ ń wò orílẹ̀ èdèkí àwọn ọlọ̀tẹ̀ má ṣe gbé ara wọn ga. Sela
8. Ẹ yin Ọlọ́run wa, ẹ̀yin ènìyàn,jẹ́ kí a mú ni gbọ́ ohun ìyìn Rẹ̀;
9. O ti dá ààbò bo ẹ̀mí wakò sì jẹ́ kí ẹsẹ̀ wa kí o yẹ̀