Sáàmù 65:6-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ìwọ tí ó dá òkè nípa agbára Rẹtí ó di ara Rẹ̀ ní àmùrè agbára

7. Ẹni tí ó mú ríru omi òkun dákẹ́ríru ariwo omi wọn,àti gìdìgìdì àwọn ènìyàn

8. Àwọn tí ó ń gbé òkèrè bẹ̀rù agbára Rẹ̀:ìwọ mú ìjáde òwúrọ̀ àti ti àṣálẹ̀ yọìwọ pé orin ayọ̀ jáde.

9. Ìwọ bẹ ayé wò, o sì bomirin;ìwọ mú ní ọ̀rọ̀ púpọ̀.Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kún fún omiláti pèsè ọkàn fún àwọn ènìyàn,nítorí ibẹ̀ ní ìwọ ti yàn án.

10. Ìwọ fi ìrinmi sí aporo Rẹìwọ tẹ́ ògúlùtù Rẹ;ìwọ fi òjò mú ilẹ̀ Rẹ rọ̀o sì bùkún ọ̀gbìn Rẹ.

11. Iwọ fi oore Rẹ de ọdún ni adé,ọ̀rá ń kan ni ipa-ọ̀nà Rẹ

Sáàmù 65