6. Agara ìkérora mi da mi tán;gbogbo òru ni mo wẹ ibùsùn mi pẹ̀lú ẹkúnmo sì fi omi rin ibùsùn mi pẹ̀lú omijé.
7. Ojú mi di aláìlera pẹ̀lú ìbànújẹ́;wọ́n kùnà nítorí gbogbo ọ̀tá mi.
8. Kúrò lọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe iṣẹ́ ibi,nítorí Olúwa ti gbọ́ igbe mi.
9. Olúwa ti gbọ́ ẹkún mi fún àánú; Olúwa ti gba àdúrà mi.
10. Gbogbo àwọn ọ̀tá mi lójú yóò tì, wọn yóò sì dààmú;wọn yóò sì yípadà nínú ìtìjú àìròtẹ́lẹ̀.