1. Èéṣé tí ìwọ fi ń ṣe féfé nínú ìwà ìkà,ìwọ alágbára ọkùnrin?Oore Ọlọ́run dúró pẹ́ títí
2. Ahọ́n Rẹ̀ ń gbìmọ̀ ìparun;ó dà bí abẹ mímú,ìwọ ẹni tí ń hùwà ìrẹ́jẹ.
3. Ìwọ fẹ́ràn ibi ju ire lọ,àti èké ju kí ó sọ òtítọ́ lọ.
4. Ìwọ fẹ́ràn ọ̀rọ̀ ìpanilára gbogbo,ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn!
5. Ọlọ́run yóò sì lù ọ́ bolẹ̀ láéláé,yóò sì dì ọ́ mú,yóò sì já ọ kúrò ni ibùjókòó Rẹyóò sì fà ọ́ tu kúrò lórí ilẹ̀ alààyè. Sela