Sáàmù 50:18-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Nígbà tí ìwọ rí olè, ìwọ dára pọ̀ mọ́-ọnìwọ sì da ara Rẹ̀ dé àwọn alágbèrè

19. Ìwọ lo ẹnu Rẹ̀ fún aburúìwọ sì ń fi ahọ́n Rẹ pète ẹ̀tàn

20. Ní ìgbà gbogbo ìwọ ń sọ̀rọ̀ sí ará-kun-rin Rẹ,ìwọ sì ń ba orúkọ ọmọ ìyá Rẹ jẹ́

21. Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ìwọ ti ṣe, mo sì dákẹ́;ìwọ rò pé mo jẹ́ irú kan náà bí ìrẹ,ṣùgbọ́n èmi yóò bá ọ wíèmi yóò sì fi ẹ̀sùn kàn ọ́ ní ojú ara Rẹ.

22. “Ǹjẹ́ ìwọ ro èyí wò, ẹ̀yin tí ó gbàgbé Ọlọ́runBí bẹ́ ẹ̀ kọ́ èmi yóò fa yin ya pẹ́rẹ́pẹ̀rẹ́láì sí ẹni tí yóò gbà yin sílẹ̀

Sáàmù 50