Sáàmù 5:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, Olúwa,kíyèsí àròyé mi.

2. Fi etí sílẹ̀ sí igbe mi fún ìrànlọ́wọ́,ọba mi àti Ọlọ́run mi,nítorí ìwọ ni mo gba àdúrà sí.

3. Ní òwúrọ̀, Olúwa, ìwọ yóò gbọ́ ohùn mi;ní òwúrọ̀ èmi yóò gbé ẹ̀bẹ̀ mi sí iwájú Rẹ̀èmi yóò sì dúró ní ìrètí.

4. Nítorí ìwọ kì í ṣe Ọlọ́run tí ó ní inú dídùn sí búburú;bẹ́ẹ̀ ni ẹni ibi kò le è bá ọ gbé.

5. Àwọn agbéraga kò le è dúró níwájú Rẹ̀;ìwọ kóríra gbogbo àwọn aṣebi.

6. Ìwọ yóò pa àwọn tí ń ṣe èké run;apani àti ẹni ẹ̀tàn ènìyànni Olúwa yóò kórìíra.

Sáàmù 5