Sáàmù 49:3-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Ẹnu mi yóò sọ̀rọ̀ ọgbọ́nìsọ láti ọkàn mi yóò mú òye wá

4. Èmi yóò yí etí mi sí òweolókùn ni èmi yóò ṣi ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ mí sílẹ̀ lójú okùn dùùrù.

5. Èéṣé ti èmi yóò bẹ̀rù nígbà tí ọjọ́ ibi déNígbà tí àwọn ènìyàn búburú àti ayan nijẹ yí mi ká,

6. Àwọn tí o gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ wọntí wọn sì ń ṣe ìlérí ni ọpọlọpọ ọrọ̀ wọn

7. Kò sí ọkùnrin tí o le ra ẹ̀mí ẹnìkejì Rẹ̀padà tàbí san owó ìràpadà fúnỌlọ́run.

8. Nítorí ìràpadà fún ẹni jẹ iyebíyekò sì sí iye owó tó tó fún sísan Rẹ̀

9. Níti ki ó máa wà títí ayéláì rí ìsà òkú.

10. Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn rí ọkùnrin ọlọ́gbọ́n tí ó kúbẹ́ẹ̀ ni aṣiwèrè àti aláìlọ́gbọ́n pẹ̀lú sègbéwọ́n sì fi ọrọ̀ wọn sílẹ̀ fún ẹlòmíràn

Sáàmù 49