Sáàmù 49:16-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Má ṣe bẹ̀rù nígbà tí ẹnikan bá di ọlọ́rọ̀Nígbà tí ìyìn ilé Rẹ̀ ń pọ̀ síi

17. nítorí kì yóò mú òun kan dání nígbà tí ó bá kú,ògo Rẹ̀ kòní báa sọ̀kálẹ̀ sí ipò òkú

18. Nígbà tí ó wà láyé, ó súre fún ọkàn ara Rẹ̀.Àwọn ènìyàn yìn ọ́ nígbà tí ìwọ ṣe rere

19. Òun yóò lọ sí ọ̀dọ̀ ìran àwọn baba Rẹàwọn tí ki yóò ri ìmọ́lẹ̀ ayé.

20. Ọkùnrin tí ó ní ọlá tí kò ní òye dàbí ẹranko tí ó ṣègbé.

Sáàmù 49