Sáàmù 45:11-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Bẹ́ẹ̀ ni ọba yóò fẹ́ ẹwà Rẹ gidigidinítorí òun ni Olúwa Rẹkí ìwọ sì máa tẹríba fún un.

12. Ọmọbìnrin ọba tirẹ̀ yóò wá pẹ̀lú ẹ̀bùnàwọn ọkùnrin ọlọ́rọ̀ yóò máa wá ojú rere Rẹ̀.

13. Gbogbo ògo ni ti ọmọbìnrin ọba ní àárin ilé Rẹ̀aṣọ ìbalẹ̀ Rẹ̀ a ṣe é lọ́sọ̀ọ́ pẹ̀lú wúrà

14. Nínú aṣọ ìbànújẹ́ iyebíye ni a mú-un wá sí ọ̀dọ̀ ọbaàwọn wúndíá ẹgbẹ́ Rẹ̀ tẹ̀ lé e wọ́n, sí mú-un tọ̀ ọ́ wá

15. Wọ́n sì mú un wá pẹ̀lú ayọ̀ àti inú dídùnwọ́n sì wọ ààfin ọba.

16. Ọmọ Rẹ̀ ni yóò gba ipò baba Rẹ̀ìwọ yóò sì fi wọ́n joyè lórí ilẹ̀ gbogbo.

17. Èmí yóò máa rántí orúkọ Rẹ̀ ní ìran gbogbonígbà náà ni orílẹ̀ èdè yóò yìn ọ́ láé àti láéláé.

Sáàmù 45