Sáàmù 44:20-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Bí àwa bá ti gbàgbé orúkọ Ọlọ́run watàbí tí a na ọwọ́ wa sí ọlọ́run àjèjì.

21. Ǹjẹ́ Ọlọ́run kì yóò rí ìdí Rẹ̀,níwọ̀n ìgbà tí ó mọ ohun ìkọ̀kò inú ọkàn?

22. Ṣíbẹ̀, nítorí Rẹ̀ àwa da àyà kọ ikú, ní ojojúmọ́a ń kà wá sí bí àgùntàn fún pípa.

23. Jí, Olúwa! Èéṣe tí ìwọ ń sùn?Dìde fún ra Rẹ! Má ṣe kọ̀ wá sílẹ̀ láéláé.

24. Èéṣe tí ìwọ ń pa ojú Rẹ mọ́tí ìwọ sì gbàgbé ìpọ́njú àti ìnira wa?

Sáàmù 44