1. Ìbùkùn ni fún ẹni tí ó ń rò ti aláìní: Olúwa yóò gbà á ni ìgbà ìpọ́njú.
2. Olúwa yóò dààbò bòó yóò sí pa ọkàn Rẹ̀ mọ́:yóò bùkún fún-un ni orí ilẹ̀kò sì ní fi sílẹ̀ fún ìfẹ́ àwọn ọ̀tá Rẹ̀.
3. Olúwa yóò gbà á lórí àkéte àìsàn Rẹ̀yóò sì mú-un padà bọ̀ sípò kúrò nínú àìsàn Rẹ̀.
4. Ní ti èmi, mo wí pé “Olúwa, ṣàánú fún mí;wò mí sàn, nítorí pé mo ti ṣẹ̀ sí ọ”.