Sáàmù 40:6-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ẹbọ àti ẹran ẹbọ ni ìwọ kò fẹ́,ìwọ ti sí mi ní etí.Ọrẹ ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ni ìwọ kò bèèrè.

7. Nígbà náà ni mo wí pé,“Èmi nìyí;nínú ìwé kíkà nìa kọ ọ nípa temí wí pé.

8. Mo ní inú dídùnláti ṣe ìfẹ́ ẹ̀ Rẹ,ìwọ Ọlọ́run mi;Òfin Rẹ̀ ń bẹ ní àyà mi.”

9. Èmi ti sọ ìròyìn ayọ̀ ti ìgbàlàláàrin àwùjọ ńlá;wòó,èmi kò pa ètè mí mọ́,gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti mọ̀,ìwọ Olúwa.

10. Èmi kò fi ìrànlọ́wọ́ ìgbàlàsin ní àyà mi,èmí ti sọ̀rọ̀ nípa òtítọ́àti ìgbàlà Rẹ̀:èmi kò sì pa ìṣeun ìfẹ́ Rẹ̀àti òtítọ́ Rẹ̀ mọ́kúrò láàrin àwọn ìjọ ńlá.

11. Ìwọ má ṣe,fa àánú Rẹ̀ tí ó rọnúsẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ mi; Olúwajẹ́ kí ìṣeun ìfẹ́ Rẹàti òtítọ́ Rẹkí ó máa pa mí mọ́títí ayérayé.

12. Nítorí pé àìníye ibini ó yí mi káàkiri,ẹ̀ṣẹ̀ mi sì dì mọ́ mi,títí tí èmi kò fi ríran mọ́;wọ́n pọ̀ ju irun orí mi lọ,àti wí pé àyà mí ti kùnà.

13. Jẹ́ kí ó wù ọ́,ìwọ Olúwa,láti gbà mí là; Olúwa,yára láti ràn mí lọ́wọ́.

Sáàmù 40