3. Ṣùgbọ́n kí ẹ mọ̀ pé, Olúwa ti ya ẹni olódodo ṣọ́tọ̀ fún ara Rẹ̀; Olúwa yóò gbọ́ nígbà tí mo bá pè é.
4. Ẹ bínú ẹ má ṣe ṣẹ̀;Nígbà tí ẹ bá wà lórí ibùsùn yín,ẹ bà ọkàn yín sọ̀rọ̀, kí ó sì dákẹ́ jẹ́.
5. Ẹ rú ẹbọ òdodokí ẹ sì gbẹ́kẹ̀ lé Olúwa.
6. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló ń béèrè pé, “Ta ni yóò ṣe rere fún wá?” Olúwa, Jẹ́ kí ojú Rẹ mọ́lẹ̀ sí wa lára,
7. Ìwọ ti fi ayọ̀ púpọ̀ kún ọkàn miju ìgbà tí hóró irúgbìn àti wáìnì tuntun wọ́n pọ̀ fún mi lọ.
8. Èmi yóò dùbúlẹ̀, èmi ó sì sùn ní àlàáfíà,nítorí ìwọ nìkan, Olúwa, ni omú mi gbé láìléwu.