3. Ṣùgbọ́n kí ẹ mọ̀ pé, Olúwa ti ya ẹni olódodo ṣọ́tọ̀ fún ara Rẹ̀; Olúwa yóò gbọ́ nígbà tí mo bá pè é.
4. Ẹ bínú ẹ má ṣe ṣẹ̀;Nígbà tí ẹ bá wà lórí ibùsùn yín,ẹ bà ọkàn yín sọ̀rọ̀, kí ó sì dákẹ́ jẹ́.
5. Ẹ rú ẹbọ òdodokí ẹ sì gbẹ́kẹ̀ lé Olúwa.
6. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló ń béèrè pé, “Ta ni yóò ṣe rere fún wá?” Olúwa, Jẹ́ kí ojú Rẹ mọ́lẹ̀ sí wa lára,