Sáàmù 38:3-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Kò sí ibi yíyè ní ara à minítorí ìbínú Rẹ;kò sí àlàáfíà nínú egungun minítorí i ẹ̀ṣẹ̀ mi.

4. Nítorí àìṣedédé miti borí mi mọ́lẹ̀;wọ́n tó ìwọ̀n bi àjàgàtí ó wúwo jù fún mi:

5. Ọgbẹ́ mi ń rùnó sì díbàjẹ́nítorí òmùgọ̀ mi;

6. Èmi ń jòwèrè:orí mi tẹ̀ ba gidigidièmi ń sọ̀fọ̀ rìn kiri ní gbogbo ọjọ́.

7. Nítorí ẹ̀gbẹ́ mi kún fún ìgbóná ti ń jó nikò sì sí ibi yíyè ní ara mi,

8. Ara mi hù, a sì wó mi jégéjégé;mo ké rora nítorí ìrúkèrúdò àyà mi.

Sáàmù 38