4. Kí wọn kí ó dààmú, kí a sì ti àwọn tí ń lépa ọkàn mi lójú:kí a sì mú wọn padà,kí a sì dààmú àwọn tí ń gbérò ìpalára mi.
5. Jẹ́ kí wọn dà bí ìyàngbò níwájú afẹ́fẹ́,kí ángẹ́lì Olúwakí ó máa lé wọn kiri.
6. Jẹ́ kí ọ̀nà wọn kí ó sókùnkùnkí ó sì máa yọ́,kí áńgẹ́lì Olúwakí ó máa lépa wọn!
7. Nítorí pé, ní àìnídìí ní wọ́n dẹàwọ̀n wọn sílẹ̀ fún mi,ní àìnídìí ni wọ́n wa kòtòfún ọkàn mi.