4. Olúwa ni mo kígbe sókè sí,ó sì dá mi lóhùn láti orí òkè mímọ́ Rẹ̀ wá.
5. Èmi dúbùú lẹ̀, mo sì sùn;mo sì tún padà jí, nítorí Olúwa ni ó ń gbé mi ró.
6. Èmi kì yóò bẹ̀rù ẹgbẹgbẹ̀rún ènìyàntí wọ́n rọ̀gbà yí mi ká.
7. Dìde, Olúwa!Gbà mí, Ọlọ́run mi!Lu gbogbo àwọn ọ̀ta mi ní àgbọ̀n;kí o sì ká eyín àwọn ènìyàn búburú.
8. Láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni ìgbàlà ti wá.Kí ìbùkún Rẹ̀ wà lóri àwọn ènìyàn Rẹ̀. Sela