Sáàmù 28:5-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Nítorí pé wọn kò ka iṣẹ́ Olúwa sí,tàbí àwọn isẹ́ ọwọ́ Rẹ̀òun ó rún wọn wọlẹ̀kò sì ní tún wọn kọ́ mọ́.

6. Alábùkún fún ni Olúwa!Nítorí pé ó ti gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.

7. Olúwa ni agbára mi àti aṣà mi;nínú Rẹ̀ ni mo gbẹ́kẹ̀lé; àní, ó sì ràn mí lọ́wọ́.ọkàn mi sì gbé sókè fún ayọ̀àni pẹ̀lú orin mi mo fi ọpẹ́ fún un.

8. Olúwa ni agbára àwọn ènìyàn Rẹ̀òun ni odi ìgbàlà àwọn àyànfẹ́ẹ Rẹ̀.

9. Ìwọ gba àwọn ènìyàn Rẹ là, kí o sì bùkún àwọn ajogún Rẹ;di olùsọ́ àgùntàn wọn, kí o sì gbé wọn lékè títí ayérayé.

Sáàmù 28